Acts 27:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Fún ọpọlọpọ ọjọ́, ọkọ̀ kò lè yára rìn. Tipátipá ni a fi dé Kinidusi. Afẹ́fẹ́ ṣe ọwọ́ òdì sí wa. Ni a bá gba ẹ̀gbẹ́ Kirete níbi tí afẹ́fẹ́ kò ti fẹ́ pupọ. A kọjá ibi tí ilẹ̀ gbọọrọ ti wọ ààrin òkun tí wọn ń pè ní Salimone.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awa nlọ jẹ́jẹ li ọjọ pipọ, ti awa fi agbara kaka de ọkankan Knidu, ti afẹfẹ kò bùn wa làye, awa lọ lẹba Krete, li ọkankan Salmone;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí a ń lọ jẹ́jẹ́ ní ọjọ́ púpọ̀, ti a fi agbára káká dé ọkánkán Nídúsì, àti nítorí tí afẹ́fẹ́ kò fún wa láàyè, a ba ẹ̀bá Kírétè lọ, lọ́kankán Sálímónì;