Acts 28:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
A rò pé ó dára kí á gbọ́ ohun tí o ní lọ́kàn, nítorí pé ó ti dé etígbọ̀ọ́ wa pé níbi gbogbo ni àwọn eniyan lòdì sí ẹgbẹ́ tí ó yàtọ̀ yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awa nfẹ gbọ́ li ẹnu rẹ ohun ti iwọ rò: nitori bi o ṣe ti ìsin iyapa yi ni, awa mọ̀ pe, nibigbogbo li a nsọ̀rọ lòdi si i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwa ń fẹ́ gbọ́ lẹ́nu rẹ ohun tí ìwọ rò nítorí bí ó ṣe ti ìsìn ìyapa yìí ní, àwa mọ̀ pé, níbi gbogbo ni a ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.”