Acts 28:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n bá dá ọjọ́ tí wọn yóo wá fún un. Nígbà tí ọjọ́ pé, pupọ ninu wọn wá kí i. Ó bá dá ọ̀rọ̀ sílẹ̀, ó ń fi tẹ̀dùntẹ̀dùn ṣe àlàyé ìjọba Ọlọrun fún wọn, ó sì ń fi ẹ̀rí tí ó wà ninu ìwé Òfin Mose ati ìwé wolii nípa Jesu hàn wọ́n láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn dá ọjọ fun u, ọ̀pọlọpọ wọn li o tọ̀ ọ wá ni ile àgbawọ rẹ̀; awọn ẹniti o sọ asọye ọrọ ijọba Ọlọrun fun, o nyi wọn lọkàn pada sipa ti Jesu, lati inu ofin Mose ati awọn woli wá, lati owurọ̀ titi o fi di aṣalẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn fi ẹnu kò lórí ọjọ́ tí wọn yóò se ìpàdé pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó tọ̀ ọ́ wa ni ilé àgbàwọ̀ rẹ̀; àwọn ẹni tí òun sọ àsọyé ọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún, ó ń yí wọn padà nípa ti Jésù láti inú òfin Mósè àti àwọn wòlíì, láti òwúrọ̀ títí ó fi di àṣálẹ́.