Acts 28:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí ọkàn àwọn eniyan yìí kò ṣí; wọ́n ti di alágbọ̀ọ́ya, wọ́n ti dijú. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn ìbá fi ojú wọn ríran, wọn ìbá fetí gbọ́ràn, òye ìbá yé wọn, wọn ìbá yipada; èmi ìbá sì wò wọ́n sàn.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti àiya awọn enia yi sebọ, etí wọn si wuwo lati fi gbọ́, oju wọn ni nwọn si ti dì: nitori ki nwọn ki o má ba fi oju wọn ri, ki nwọn ki o má ba fi etí wọn gbọ́, ati ki nwọn ki o má ba fi ọkàn wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ati ki emi ki o má ba mu wọn larada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ti àyà àwọn ènìyàn yìí yigbì, etí wọn sì wúwo láti fi gbọ́, ojú wọn ni wọn sì ti di. Nítorí kí wọn má ba à fi ojú wọn rí, kí wọn má ba à fi etí wọn gbọ́, àti kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀, kí wọn má ba à yípadà, àti kí èmi má ba à mú wọn láradá.’