Acts 3:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Peteru rí wọn, ó bi àwọn eniyan pé, “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, kí ló dé tí èyí fi yà yín lẹ́nu? Kí ló dé tí ẹ fi tẹjú mọ́ wa bí ẹni pé nípa agbára wa tabi nítorí pé a jẹ́ olùfọkànsìn ni a fi mú kí ọkunrin yìí rìn?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Peteru si ri i, o dahùn wi fun awọn enia pe, Ẹnyin enia Israeli, ẽṣe ti ha fi nṣe nyin si eyi? tabi ẽṣe ti ẹnyin fi tẹjumọ́ wa, bi ẹnipe agbara tabi iwa-mimọ́ wa li awa fi ṣe ti ọkunrin yi fi nrin?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Pétérù sì rí i, ó dáhùn, ó wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, è é ṣe tí háà fi ń ṣe yín sí èyí? Tàbí è é ṣe ti ẹ̀yin fi tẹjúmọ́ wa, bí ẹni pé agbára tàbí ìwà mímọ́ wa ni àwa fi ṣe é ti ọkùnrin yìí fi ń rìn?