Acts 3:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Orúkọ Jesu ati igbagbọ ninu orúkọ yìí ni ó mú ọkunrin tí ẹ rí yìí lára dá. Ẹ ṣá mọ̀ ọ́n. Igbagbọ ninu rẹ̀ ni ó fún ọkunrin yìí ní ìlera patapata, gẹ́gẹ́ bí gbogbo yín ti rí i fúnra yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati orukọ rẹ̀, nipa igbagbọ́ ninu orukọ rẹ̀, on li o mu ọkunrin yi lara le, ẹniti ẹnyin ri ti ẹ si mọ̀: ati igbagbọ́ nipa rẹ̀ li o fun u ni dida ara ṣáṣa yi li oju gbogbo nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípa ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jésù, òun ni ó mú ọkùnrin yìí láradá, ẹni tí ẹ̀yin rí, tí ẹ sì mọ̀. Orúkọ Jésù àti ìgbàgbọ́ tí ó wá nípa rẹ̀ ni ó fún un ní ìlera pípé ṣáṣá yìí ni ojú gbogbo yín.