Acts 3:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀yin gan-an ni ọmọ àwọn wolii; nítorí tiyín ni Ọlọrun ṣe bá àwọn baba yín dá majẹmu, nígbà tí ó sọ fún Abrahamu pé, ‘Nípa ọmọ rẹ ni n óo ṣe bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin li ọmọ awọn woli, ati ti majẹmu tí Ọlọrun ti ba awọn baba nyin dá nigbati o wi fun Abrahamu pe, Ati ninu irú-ọmọ rẹ li a ti fi ibukun fun gbogbo idile aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin ni ọmọ àwọn wòlíì, àti ti májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti bá àwọn baba yín dá nígbà tí ó wí fún Ábúráhámù pé, ‘Láti ipasẹ̀ irú àwọn ọmọ rẹ̀ ni a ó ti bùkún fún gbogbo ìdílé ayé.’