Acts 4:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ẹ jẹ́ kí ó hàn sí gbogbo yín ati gbogbo eniyan Israẹli pé, ọkunrin yìí dúró níwájú yín pẹlu ara líle nítorí orúkọ Jesu Kristi ará Nasarẹti, ẹni tí ẹ kàn mọ́ agbelebu, tí Ọlọrun jí dìde kúrò ninu òkú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki eyi ki o yé gbogbo nyin ati gbogbo enia Israeli pe, li orukọ Jesu Kristi ti Nasareti, ti ẹnyin kàn mọ agbelebu, ti Ọlọrun gbé dide kuro ninu okú, nipa rẹ̀ li ọkunrin yi fi duro niwaju nyin ni dida ara ṣaṣa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí èyí yé gbogbo yín àti gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì pé, ni orúkọ Jésù Kírísítì ti Násárétì, tí ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, tí Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, nípa rẹ̀ ni ọkùnrin yìí fi dúró níwájú yín ni ara dídá-ṣáṣá.