Acts 4:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n rí ìgboyà Peteru ati ti Johanu, tí wọ́n wòye pé wọn kò mọ ìwé àtipé òpè eniyan ni wọ́n, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n ṣe akiyesi wọn pé wọ́n ti wà pẹlu Jesu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn si kiyesi igboiya Peteru on Johanu, ti nwọn si mọ̀ pe, alaikẹkọ ati òpe enia ni nwọn, ẹnu yà wọn; nwọn si woye wọn pe, nwọn a ti ma ba Jesu gbé.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n sì kíyèsí ìgboyà Pétérù àti Jòhánù, tí wọ́n mọ̀ pé, aláìkẹ́kọ̀ọ́ àti òpè ènìyàn ni wọn, ẹnu yà wọ́n, wọ́n sì wòye pé, wọ́n ti ń bá Jésù gbé.