Acts 4:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Kí ni a óo ṣe sí àwọn ọkunrin wọnyi o? Nítorí ó hàn lónìí sí gbogbo àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu pé wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abàmì. A kò sì lè wí pé èyí kò rí bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wipe, Kili a o ti ṣe awọn ọkunrin wọnyi? ti pe iṣẹ àmi ti o daju ti ọwọ́ wọn ṣe, o hàn gbangba fun gbogbo awọn ti ngbé Jerusalemu; awa kò si le sẹ́ ẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wí pé, “Kí ni a ó ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí? Ní ti pé iṣẹ́ àmì tí ó dájú tí ọwọ́ wọn ṣe, ó hàn gbangba fún gbogbo àwọn tí ń gbé Jerúsálémù; àwa kò sì lè ṣe èyí.