Acts 4:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí òdodo ni pé Hẹrọdu ati Pọntiu Pilatu pẹlu àwọn tí kì í ṣe Juu ati àwọn eniyan Israẹli péjọpọ̀ ní ìlú yìí, wọ́n ṣe ohun tí ó lòdì sí ọmọ mímọ́ rẹ, Jesu tí o ti fi òróró yàn ní Mesaya,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitõtọ sá ni, si Jesu Ọmọ mimọ́ rẹ, ẹniti iwọ ti fi oróro yàn, ati Herodu, ati Pontiu Pilatu, pẹlu awọn keferi, ati awọn enia Israeli pejọ si,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àní nítòótọ́ ní Hẹ́rọ́dù, àti Pọ́ńtíù Pílátù, pẹ̀lú àwọn aláìkọlà àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì kó ara wọn jọ ní ìlú yìí láti dìtẹ̀ sí Jésù Ìrànṣẹ́ mímọ́ rẹ, ẹni tí ìwọ ti fi òróró yàn,