Acts 5:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ni òun náà bá ṣubú lulẹ̀ lẹsẹkẹsẹ níwájú Peteru, ó bá kú. Àwọn géńdé bá wọlé, wọ́n rí òkú rẹ̀. Wọ́n bá gbé e jáde, wọ́n sì sin ín sí ẹ̀bá ọkọ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣubu lulẹ li ẹsẹ rẹ̀ lojukanna, o si kú: awọn ọdọmọkunrin si wọle, nwọn bá a o kú, nwọn si gbé e jade, nwọn sin i lẹba ọkọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lójúkan náà ó sì ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì kú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì wọlé wọ́n bá a ní òkú, wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sín in lẹ́bá ọkọ rẹ̀.