Acts 5:37 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn èyí, Judasi kan, ará Galili, dìde ní àkókò tí à ń kọ orúkọ àwọn eniyan sílẹ̀. Àwọn eniyan tẹ̀lé e. Ṣugbọn wọ́n pa á, wọ́n sì tú gbogbo àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ká.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin ọkunrin yi ni Juda ti Galili dide lakoko kikà enia, o si fà enia pipọ lẹhin rẹ̀: on pẹlu ṣegbé; ati gbogbo iye awọn ti o gbà tirẹ̀, a fọn wọn ká.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ọkùnrin yìí ni Júdà ti Gálílì dìde ni àkókò kíka àwọn ènìyàn, ó sì fa ẹni púpọ̀ lẹ́yìn rẹ̀; òun pẹ̀lú ṣègbé; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ ni a fọ́nká.