Acts 6:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó yá, tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń pọ̀ sí i, ìkùnsínú bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn tí ó ń sọ èdè Giriki ati àwọn tí ó ń sọ èdè Heberu, nítorí wọ́n ń fojú fo àwọn opó àwọn tí ń sọ èdè Giriki dá, nígbà tí wọ́n bá ń pín àwọn nǹkan ní ojoojumọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NJẸ li ọjọ wọnni, nigbati iye awọn ọmọ-ẹhin npọ̀ si i, ikùn-sinu wà ninu awọn Hellene si awọn Heberu, nitoriti a nṣe igbagbé awọn opó wọn ni ipinfunni ojojumọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ ní ọjọ́ wọ̀nyí, nígbà tí iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i, ìkùn-sínú wà ní àárin àwọn Gíríkì tí se Júù àti àwọn Hébérù tí se Júù, nítorí tí a gbàgbé nípa ti àwọn opó wọn nínú ìpín-fúnni ojoojúmọ́.