Acts 6:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀rọ̀ yìí dára lójú gbogbo àwùjọ, wọ́n bá yan Stefanu. Stefanu yìí jẹ́ onigbagbọ tọkàntọkàn, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Wọ́n yan Filipi náà ati Prokoru ati Nikanọ ati Timoni ati Pamena ati Nikolausi ará Antioku tí ó ti gba ẹ̀sìn àwọn Juu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀rọ na si tọ́ loju gbogbo ijọ: nwọn si yàn Stefanu, ọkunrin ti o kún fun igbagbọ́ ati fun Ẹmí Mimọ́, ati Filippi ati Prokoru, ati Nikanoru, ati Timoni, ati Parmena, ati Nikola alawọṣe Ju ara Antioku:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú gbogbo ìjọ; wọ́n sì yan Sítéfánù, ọkùnrin tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti fún Ẹ̀mí-Mímọ́ àti Fílípì, àti Pírókórù, àti Níkánórù, àti Tímónì, àti Páríménà, àti Níkólásì aláwọ̀se Júù ara Ańtíókù.