Acts 6:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn kan wá láti ilé ìpàdé kan tí à ń pè ní ti àwọn Olómìnira, ti àwọn ará Kurene ati àwọn ará Alẹkisandria; wọ́n tako Stefanu. Àwọn tí wọ́n wá láti Silisia ati láti Esia náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a jiyàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn kan dide ninu awọn ti sinagogu, ti a npè ni ti awọn Libertine, ati ti ara Kirene, ati ti ara Aleksandria, ati ninu awọn ara Kilikia, ati ti Asia nwọn mba Stefanu jiyàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn kan dìde nínú àwọn ti ń se ara sínágógù, tí a ń pè ní Líbátaínì. Àwọn Júù Kírénè àti ti Alekisáńdíríà àti ti Kílíkíà, àti ti Ásíà wá, wọ́n ń bá Sítéfánù jiyàn,