Acts 7:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọlọrun yọ ọ́ kúrò ninu gbogbo ìpọ́njú tí ó rí. Nígbà tí ó yọ siwaju Farao, ọba Ijipti, Ọlọrun fún un lọ́gbọ́n, ó sì jẹ́ kí ó rí ojú àánú ọba Ijipti. Farao bá fi jẹ gomina lórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti ati lórí ààfin ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si yọ ọ kuro ninu ipọnju rẹ̀ gbogbo, o si fun u li ojurere ati ọgbọ́n li oju Farao ọba Egipti; on si fi i jẹ bãlẹ Egipti ati gbogbo ile rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ó sì yọ ọ́ kúrò nínú ìpọ́njú rẹ̀ gbogbo. Ó sì fún Jósẹ́fù ní ọgbọ́n, ó sì mú kí ó rí ojúrere Fáráò ọba Íjíbítì; òun sì fi jẹ baálẹ̀ Íjíbítì àti gbogbo ilé rẹ̀.