Acts 7:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n gbé òkú wọn lọ sí Ṣekemu, wọ́n sin wọ́n sinu ibojì tí Abrahamu fowó rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori ní Ṣekemu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si gbe wọn lọ si Sikemu, a si tẹ́ wọn sinu ibojì ti Abrahamu rà ni iye-owo fadaka lọwọ awọn ọmọ Emoru baba Sikemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A sì gbé òkú wọn padà wá sí Ṣékémù, a sì tẹ́ wọn sínú ibojì ti Ábúráhámù rà ni ọwọ́ àwọn ọmọ Ámórì ní Sékémù ní iye-owó wúrà kan.