Acts 7:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó yọ sí àwọn kan tí wọn ń jà. Ó bá ní kí òun parí ìjà fún wọn. Ó ní, ‘Ẹ̀yin ará, arakunrin ara yín ni ẹ̀ ń ṣe. Kí ló dé tí ẹ̀ ń lu ara yín?’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si di ijọ keji o yọ si wọn bi nwọn ti njà, on iba si pari rẹ̀ fun wọn, o wipe, Alàgba, ará li ẹnyin; ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe ohun ti kò tọ́ si ara nyin?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kejì Mósè yọ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjì bí wọ́n ti ń jà. Òun ì bá sí parí rẹ̀ fún wọn. Ó wí pé, ‘Ènìyàn mi, ará ni ẹ̀yin; è é ṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ sí ara yín?’