Acts 7:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọlọrun wá bá a dá majẹmu, ó fi ilà kíkọ ṣe àmì majẹmu náà. Nígbà tí ó bí Isaaki, ó kọ ọ́ nílà ní ọjọ́ kẹjọ. Isaaki bí Jakọbu. Jakọbu bí àwọn baba-ńlá wa mejila.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si fun u ni majẹmu ikọlà: bẹ̃li Abrahamu bí Isaaki, o kọ ọ ni ilà ni ijọ kẹjọ; Isaaki si bí Jakọbu; Jakọbu si bi awọn baba nla mejila.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì fún Ábúráhámù ni májẹ̀mú ìkọlà. Ábúráhámù bí Ísáákì, ó kọ ọ́ ní ilà-abẹ́ ni ijọ́ kẹjọ tí ó bí i. Ísáákì sí bí Jákọ́bù, Jákọ́bù sì bí àwọn baba ńlá méjìlá.