Acts 8:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Saulu bá wọn lọ́wọ́ sí ikú rẹ̀. Láti ọjọ́ náà ni inúnibíni ńlá ti bẹ̀rẹ̀ sí ìjọ tí ó wà ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn onigbagbọ bá túká lọ sí gbogbo agbègbè Judia ati Samaria. Àwọn aposteli nìkan ni kò kúrò ní ìlú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
SAULU si li ohùn si ikú rẹ̀. Li akoko na, inunibini nla kan dide si ijọ ti o wà ni Jerusalemu; a si tú gbogbo wọn kalẹ já àgbegbe Judea on Samaria, afi awọn aposteli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sọ́ọ̀lù sì wà níbẹ̀, ó sì ní ohùn sí ikú rẹ̀. Ní àkókò náà, inúnibini ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerúsálémù, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Jùdíà àti Samaríà, àyàfi àwọn àpósítélì.