Acts 9:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ó gba ìwé lọ́dọ̀ rẹ̀ láti lọ sí àwọn ilé ìpàdé tí ó wà ní Damasku. Ìwé yìí fún un ní àṣẹ pé bí ó bá rí àwọn tí ń tẹ̀lé ọ̀nà ẹ̀sìn yìí, ìbáà ṣe ọkunrin ìbáà ṣe obinrin, kí ó dè wọ́n, kí ó sì fà wọ́n wá sí Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O bẽre iwe lọwọ rẹ̀ si Damasku si awọn sinagogu pe, bi on ba ri ẹnikẹni ti mbẹ li Ọna yi, iba ṣe ọkunrin, tabi obinrin, ki on le mu wọn ni didè wá si Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ó bèèrè ìwé lọ́wọ́ rẹ̀ sí sínágọ́gù tí ń bẹ ní ìlú Dámásíkù pé, bí òun bá rí ẹnikẹ́ni tí ń bẹ ni Ọ̀nà yìí, ìbaà ṣe ọkùnrin, tàbí obìnrin, kí òun lè mú wọn ní dídè wá sí Jerúsálémù.