Acts 9:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Saulu gbọ́ nípa ète wọn. Wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnu odi ìlú tọ̀sán-tòru kí wọ́n baà lè pa á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ìditẹ̀ wọn di mimọ̀ fun Saulu. Nwọn si nṣọ ẹnu-bode pẹlu li ọsán ati li oru lati pa a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ìdìtẹ̀ wọn di mímọ̀ fún Ṣọ́ọ̀lù. Wọ́n sì ń sọ́ ẹnu-bodè pẹ̀lú lọ́san àti lóru, wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa á.