Acts 9:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Banaba mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó ròyìn fún wọn bí ó ti rí Oluwa lọ́nà, bí Oluwa ti bá a sọ̀rọ̀, ati bí ó ti fi ìgboyà waasu lórúkọ Jesu ní Damasku.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Barnaba mu u, o si sìn i lọ sọdọ awọn aposteli, o si sọ fun awọn bi o ti ri Oluwa li ọ̀na, ati pe o ti ba a sọ̀rọ, ati bi o ti fi igboiya wasu ni Damasku li orukọ Jesu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Bánábà mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ àwọn àpósítélì, ó sì sọ fún wọn bí ó ti rí Olúwa ní ọ̀nà, àti bí ó ti fi ìgboyà wàásù ní Dámásíkù ní orúkọ Jésù.