Acts 9:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọmọ-ẹ̀yìn kan wà ní Jọpa, tí ó jẹ́ obinrin, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tabita, tabi Dọkasi ní èdè Giriki. (Ìtumọ̀ rẹ̀ ni èkùlù.) Obinrin yìí jẹ́ ẹnìkan tíí máa ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ rere, ó sì láàánú pupọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ-ẹhin kan si wà ni Joppa ti a npè ni Tabita, ni itumọ̀ rẹ̀ ti a npè ni Dorka: obinrin yi pọ̀ ni iṣẹ ore, ati itọrẹ-ãnu ti o ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọmọ-ẹyìn kan sí wà ní Jópà ti a ń pè ni Tàbítà, èyí tí ó túmọ̀ sí Dọ́kásì; obìnrin yìí pọ̀ ni iṣẹ́ oore, àti ìtọrẹ-àánú ṣíṣe.