Acts 9:40 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Peteru bá ti gbogbo wọn jáde, ó kúnlẹ̀, ó gbadura. Ó bá kọjú sí òkú náà, ó ní, “Tabita, dìde.” Ni Tabita bá lajú, ó rí Peteru, ó bá dìde jókòó.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Peteru ti gbogbo wọn sode, o si kunlẹ, o si gbadura; o si yipada si okú, o ni, Tabita, dide. O si là oju rẹ̀: nigbati o si ri Peteru, o dide joko.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Pétérù ti gbogbo wọn sóde, ó sì kúnlẹ̀, ó sí gbàdúrà; ó sì yípadà sí òkú, ó ní “Tàbítà, dìde.” Ó sì la ojú rẹ̀: nígbà tí ó sì rí Pétérù, ó dìde jókòó.