Amos 1:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní: “Àwọn ará Edomu ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n dojú idà kọ arakunrin wọn, láìṣàánú wọn, wọ́n bínú kọjá ààlà, títí lae sì ni ìrúnú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Edomu, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori o fi idà lepa arakunrin rẹ̀, o si gbe gbogbo ãnu sọnù; ibinu rẹ̀ si nfaniya titi, o si pa ibinu rẹ̀ mọ titi lai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Édómù, àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà Nítorí òhun fi idà lépa arákùnrin rẹ̀, Ó sì gbé gbogbo àánú sọnù ìbínú rẹ̀ sì ń faniya títí ó sì pa ìbínú rẹ̀ bí èéfín mọ́