Amos 1:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní: “Àwọn ará Amoni ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; wọ́n fi ìwà wọ̀bìà bẹ́ inú àwọn aboyún ilẹ̀ Gileadi, láti gba ilẹ̀ kún ilẹ̀ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti awọn ọmọ Ammoni, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti là inu awọn aboyun Gileadi, ki nwọn le ba mu agbègbe wọn tobi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Ámónì àní mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà, Nítorí wọn ti la inú àwọn aboyún Gílíádì kí wọ́n ba à lè fẹ ilẹ̀ wọn sẹ́yìn.