Amos 1:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo fọ́ ìlẹ̀kùn odi ìlú Damasku. N óo sì pa gbogbo àwọn ará àfonífojì Afeni run. Wọn óo mú ọba Betedeni lọ sí ìgbèkùn; òun ati àwọn ará Siria yóo lọ sí ìgbèkùn ní ilẹ̀ Kiri.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o ṣẹ ọpá idabu Damasku pẹlu, emi o si ke ará pẹ̀tẹlẹ Afeni kuro, ati ẹniti o dì ọpá alade nì mu kuro ni ile Edeni: awọn enia Siria yio si lọ si igbèkun si Kiri, ni Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá ìdáàbú Dámásíkù; Èmi yóò sì pa ọba tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Áfénì run Àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé mú ní Bẹti-Édénì. Àwọn ará a Árámù yóò lọ sí ìgbèkùn sí Kírì,” ni OLÚWA wí.