Amos 1:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo pa gbogbo àwọn ará Aṣidodu run ati ọba Aṣikeloni; n óo jẹ ìlú Ekironi níyà, àwọn ará Filistia yòókù yóo sì ṣègbé.” OLUWA Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si ke ara Aṣdodi kuro, ati ẹniti o di ọpá alade mu kuro ni Aṣkeloni, emi o si yi ọwọ́ mi si Ekroni; iyokù ninu awọn ara Filistia yio ṣegbe, li Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò ké àwọn olùgbé Ásódì kúrò. Àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé ní Ákélónì mú. Èmi yóò yí ọwọ́ mi sí Ékírónì títí tí ìyókù Fílístínì yóò fi ṣègbé,” ni OLÚWA Ọlọ́run wí.