Amos 2:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní: “Àwọn ará Moabu ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n sọná sí egungun ọba Edomu, wọ́n sun ún, ó jóná ráúráú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
BAYI li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Moabu, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori o ti sun egungun ọba Edomu di ẽrú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí; “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Móábù, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà, Nítorí ó ti sun-ún, di eérú, egungun ọba Édómù