Amos 2:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo yan àwọn kan ninu àwọn ọmọ yín ní wolii mi, mo sì yan àwọn mìíràn ninu wọn ní Nasiri. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli? Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si gbe ninu ọmọkunrin nyin dide lati jẹ woli, ati ninu awọn ọdọmọkunrin nyin lati jẹ Nasarite. Bẹ̃ ki o ri, ẹnyin ọmọ Israeli? li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi sì tún gbé àwọn wòlíì dìde láàárin àwọn ọmọ yín àti láàárin àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín láti jẹ Násárátì èyí kò ha jẹ́ òtítọ́ bí ará Ísírẹ́lì?” ni OLÚWA wí.