Amos 2:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní: “Àwọn ará Juda ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n ti kọ òfin èmi OLUWA sílẹ̀, wọn kò sì rìn ní ìlànà mi. Àwọn oriṣa irọ́ tí àwọn baba wọn ń bọ, ti ṣì wọ́n lọ́nà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Juda, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti gàn ofin Oluwa, nwọn kò si pa aṣẹ rẹ̀ mọ, eke wọn si ti mu wọn ṣina, eyiti awọn baba wọn ti tẹ̀le.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Júdà, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà Nítorí wọn ti kọ òfin OLÚWA sílẹ̀ wọn kò sì pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́ Nítorí àwọn òrìṣà ti sì wọ́n lọ́nà Òrìṣà tí àwọn Baba ńlá wọn ń tẹ̀lé