Amos 2:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n rẹ́ àwọn talaka jẹ, wọ́n sì yí ẹjọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ po. Baba ati ọmọ ń bá ẹrubinrin kanṣoṣo lòpọ̀, wọ́n sì ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn tẹ ori talaka sinu eruku ilẹ, nwọn si yi ọ̀na ọlọkàn tutù po: ati ọmọ ati baba rẹ̀ nwọle tọ̀ wundia kan, lati bà orukọ mimọ́ mi jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n fi ẹsẹ̀ tẹ orí àwọn talákà mọ́lẹ̀ bí wọ́n ti ń tẹ ẹrùpẹ̀ ilẹ̀ tí wọ́n sì fi òtítọ́ du àwọn tí a ni lára Baba àti ọmọ ń wọlé tọ wúndíá kan náà Láti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́