Amos 2:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bẹ́ẹ̀ sì ni èmi ni mo pa àwọn ará Amori run fún wọn, àwọn géńdé, tí wọ́n ga bí igi kedari, tí wọ́n sì lágbára bí igi oaku; mo run wọ́n tèsotèso, tigbòǹgbò-tigbòǹgbò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn mo pa ará Amori run niwaju wọn, giga ẹniti o dàbi giga igi-kedari, on si le bi igi-oaku; ṣugbọn mo pa eso rẹ̀ run lati oke wá, ati egbò rẹ̀ lati isalẹ wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Mo pa àwọn ará Ámórì run níwájú wọn gíga ẹni tí ó dàbí igi Kédárì. Òun sì le koko bí igi Óákù mo pa èso rẹ̀ run láti òkè wá àti egbò rẹ̀ láti ìṣàlẹ̀ wá.