Amos 3:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní: “Bí olùṣọ́-aguntan tií rí àjẹkù ẹsẹ̀ meji péré, tabi etí kan gbà kalẹ̀ lẹ́nu kinniun, ninu odidi àgbò, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn ọmọ Israẹli, tí ń gbé Samaria: díẹ̀ ninu wọn ni yóo là, àwọn tí wọn ń sùn lórí ibùsùn olówó iyebíye.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi; gẹgẹ bi oluṣọ-agùtan iti gbà itan meji kuro li ẹnu kiniun, tabi ẹlà eti kan; bẹ̃li a o mu awọn ọmọ Israeli ti ngbe Samaria kuro ni igun akete, ati ni aṣọ Damasku irọ̀gbọku.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Bí olusọ-àgùntan ti ń gbà itan méjì kúrò ní ẹnu kìnnìun tàbí ẹ̀là eti kan bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí ń gbé Samáríà kúrò ní igun ibùsùn wọn ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Dámásíkù.”