Amos 4:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin obinrin Samaria, ẹ̀yin tí ẹ sanra bíi mààlúù Baṣani, tí ẹ wà lórí òkè Samaria, tí ẹ̀ ń ni àwọn aláìní lára, tí ẹ̀ ń tẹ àwọn talaka ní àtẹ̀rẹ́, tí ẹ̀ ń wí fún àwọn ọkọ yín pé, “Ẹ gbé ọtí wá kí á mu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ yi, ẹnyin ọmọ malu Baṣan, ti o wà li oke nla Samaria, ti o nni talakà lara, ti o ntẹ̀ alaini rẹ́, ti o nwi fun oluwa wọn pe, Gbe wá, ki a si mu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin màlúù Báṣánì lórí òkè Samáríà, ẹ̀yin obìnrin tí ó ń ni talákà lára, tí ó ń tẹ aláìní mọ́lẹ̀, tí ó wí fún ọkọ rẹ̀, “Gbé wá kí a sì mu!”