Amos 4:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ gbọ́! Ọlọrun ni ó dá òkè ńlá ati afẹ́fẹ́, tí ń fi èrò ọkàn rẹ̀ han eniyan, Ọlọrun ní ń sọ òwúrọ̀ di òru, tí sì ń rìn níbi gíga-gíga ayé; OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori sa wò o, ẹniti o dá awọn oke nla, ti o si dá afẹ̃fẹ, ti o si sọ fun enia ohun ti erò inu rẹ̀ jasi, ti o sọ owurọ̀ di òkunkun, ti o si tẹ̀ ibi giga aiye mọlẹ, Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tí ó dá àwọn òkè tí ó dá afẹ́fẹ́ tí ó sì fi èrò rẹ̀ hàn sí ènìyàn, ẹni tí ó yípadà sí òkùnkùn tí ó sì tẹ ibi gíga ayé. OLÚWA Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo ni orúkọ rẹ̀.