Amos 4:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun ti fi ìwà mímọ́ rẹ̀ búra pé, “Ọjọ́ ń bọ̀, tí wọn óo fi ìwọ̀ fà yín lọ, gbogbo yín pátá ni wọn óo fi ìwọ̀ ẹja fà lọ, láì ku ẹnìkan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa Ọlọrun ti bura ninu iwà-mimọ́ rẹ̀, pe, Sa wò o, ọjọ wọnni yio de ba nyin, ti on o fi ìwọ gbe nyin kuro, yio si fi ìwọ-ẹja gbe iran nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA Ọlọ́run ti fi ìwà mímọ́ rẹ̀ búra: “Àkókò náà yóò dé nítòótọ́ nígbà tí a ó fi ìwọ̀ mú un yín lọ, ẹni tí ó kẹ́yìn pẹ̀lú ìwọ̀ ẹja.