Amos 5:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, àní OLUWA ní: “Ẹkún yóo wà ní gbogbo ìta gbangba, wọn yóo sì máa kọ ‘Háà! Háà!’ nígboro. Wọn yóo pe àwọn àgbẹ̀ pàápàá, ati àwọn tí wọn ń fi ẹkún sísun ṣe iṣẹ́ ṣe, láti wá sọkún àwọn tí wọ́n kú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ani Oluwa wi bayi pe, Ẹkun yio wà ni gbogbo ita; nwọn o si ma wi ni gbogbo òpopó ọ̀na pe, Ã! ã! nwọn o si pè agbẹ̀ si iṣọ̀fọ, ati iru awọn ti o gbọ́n lati pohùnrére si isọkún.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èyí ni ohun tí OLÚWA, Ọlọ́run alágbára wí: “Ẹkún yóò wà ní àwọn òpópónà igbe ìnira yóò sì wà ní àwọn gbàgede ìlú A ó kó àwọn àgbẹ̀ jọ láti sunkún Àti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ láti pohùnréré ẹkún