Amos 5:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun ní: “Ninu ẹgbẹrun ọmọ ogun tí ìlú Israẹli kan bá rán jáde, ọgọrun-un péré ni yóo kù. Ninu ọgọrun-un tí ìlú mìíràn bá rán jáde, mẹ́wàá péré ni yóo kù.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ilu ti o jade lọ li ẹgbẹrun yio ṣikù ọgọrun; eyiti o si jade lọ li ọgọrun yio ṣikù mẹwa, fun ile Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA ọ̀gá ògo wí: “Ìlú tí ẹgbẹ̀rún alágbára ti jáde, yóò dín ku ọgọ́run ní Ísírẹ́lì. Ìlú tí ọgọ́run alàgbà ti jáde yóò ṣẹ́ku ẹni mẹ́wàá.”