Amos 6:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìsìnkú bá kó eegun òkú jáde, tí ó bá bi àwọn eniyan tí ó kù ninu ilé pé, “Ǹjẹ́ ó ku ẹnikẹ́ni mọ́?” Wọn yóo dá a lóhùn pé, “Rárá.” Nígbà náà ni olùdarí ìsìnkú yóo sọ pé, “Ẹ dákẹ́, ẹ ṣọ́ra, a kò gbọdọ̀ tilẹ̀ dárúkọ OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati arakunrin rẹ̀, ati ẹniti o nfi i joná, lati kó egungun wọnni jade kuro ninu ile, yio gbe e, yio si bi ẹniti o wà li ẹba ile lere pe, O ha tun kù ẹnikan pẹlu rẹ? On o si wipe, Bẹ̃kọ̀. Nigbana li on o wipe, Pa ẹnu rẹ mọ: nitoripe awa kò gbọdọ da orukọ Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béérè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó farapamọ́ níbẹ̀, “Njẹ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín?” tí ó bá sì dáhùn wí pé, “Rárá,” nígbà náà ni yóò wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ OLÚWA.”