Amos 6:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, n óo rán orílẹ̀-èdè kan láti pọn yín lójú, wọn yóo sì fìyà jẹ yín láti ibodè Hamati, títí dé odò Araba.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn kiyesi i, emi o gbe orilẹ-ède kan dide si nyin, ẹnyin ile Israeli, li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi; nwọn o si pọ́n nyin loju lati iwọle Hamati, titi de odò pẹ̀tẹlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí OLÚWA Ọlọ́run alágbára wí pé, “Èmi yóò gbé orílẹ̀-èdè kan dìde sí ọ ìwọ Ísírẹ́lì, tí yóò máa ni ọ́ lára ní gbogbo ọ̀nà láti ẹnu ọ̀nà ìwọlé Hámátì títí dé àfonífojì aginjù.”