Amos 6:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ lọ wo ìlú Kane; ẹ ti ibẹ̀ lọ sí Hamati, ìlú ńlá nì, lẹ́yìn náà ẹ lọ sí ìlú Gati, ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia. Ṣé wọ́n sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yín lọ ni? Tabi agbègbè wọn tóbi ju tiyín lọ?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ kọja si Kalne, si wò; ẹ si ti ibẹ̀ lọ si Hamati nla: lẹhìn na ẹ sọ̀kalẹ lọ si Gati ti awọn Filistini: nwọn ha san jù ilẹ ọba wọnyi lọ? tabi agbègbe wọn ha tobi jù agbègbe nyin lọ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ lọ Kálínì kí ẹ lọ wò ó Kí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí Ámátì ìlú ńlá a nì. Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ Gátì ní ilẹ̀ Fílístínì Ǹjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ? Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju ti yín lọ bí?