Amos 6:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn tí ń sùn sórí ibùsùn tí wọ́n fi eyín erin ṣe gbé! Àwọn tí wọ́n nà kalẹ̀ lórí ìrọ̀gbọ̀kú wọn, tí wọn ń jẹ ẹran ọ̀dọ́ aguntan, ati ti ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù láti inú agbo ẹran wọn!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ti o ndùbulẹ lori akete ehin-erin, ti nwọn si nnà ara wọn lori irọ̀gbọku wọn, ti nwọn njẹ ọdọ-agùtan inu agbo, ati ẹgbọ̀rọ malu inu agbo;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin sùn lé ibusùn tí a fi eyín erin ṣe Ẹ sì tan ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn Ẹ̀yin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn yín jẹ Ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrin agbo wọn jẹ