Amos 6:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ti fi ara rẹ̀ búra, ó ní: “Mo kórìíra ìwà ìgbéraga Jakọbu, ati gbogbo àwọn ibi ààbò rẹ̀; n óo mú ọwọ́ kúrò lọ́rọ̀ ìlú náà ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa Ọlọrun ti fi ara rẹ̀ bura, li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ ogun wi, Emi korira ọlanla Jakobu, mo si korira ãfin rẹ̀: nitorina li emi o ṣe fi ilu na, ati ohun gbogbo ti o wà ninu rẹ̀ tọrẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA ọ̀gá ògo ti búra fúnra rẹ̀ OLÚWA Ọlọ́run alágbára sì ti wí pé: “Mo kórìíra ìgbéraga Jákọ́bù n kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀ Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.”