Amos 7:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ń wí pé, ‘Jeroboamu yóo kú sójú ogun, gbogbo ilé Israẹli ni a óo sì kó lẹ́rú lọ.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Amosi wi, Jeroboamu yio ti ipa idà kú, nitõtọ Israeli li a o si fà lọ si igbèkun kuro ni ilẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èyí ni ohun ti Ámosì ń sọ: “ ‘Jéróbóámù yóò ti ipa idà kú, Lóótọ́ Ísírẹ́lì yóò lọ sí ìgbèkùn, jìnnà kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ”