Amos 7:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn eṣú náà ti jẹ gbogbo koríko ilẹ̀ náà tán, mo ní, “OLUWA Ọlọrun, jọ̀wọ́ dáríjì àwọn eniyan rẹ. Báwo ni àwọn ọmọ Jakọbu yóo ṣe là, nítorí pé wọ́n kéré níye?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, ti nwọn jẹ koriko ilẹ na tan, nigbana ni mo wipe, Oluwa Ọlọrun, darijì, emi bẹ̀ ọ: Jakobu yio ha ṣe le dide? nitori ẹnikekere li on.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n jẹ koríko ilẹ̀ náà mọ́ féfé nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “OLÚWA Ọlọ́run, mo bẹ̀ ọ́, dáríjìn! Báwo ni Jákọ́bù yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”