Amos 7:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun tún fi ìran mìíràn hàn mí: mo rí i tí Ọlọrun pe iná láti fi jẹ àwọn eniyan rẹ̀ níyà. Iná náà jó ibú omi, ráúráú ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jó ilẹ̀ pàápàá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa Ọlọrun ti fi hàn mi: si wò o, Oluwa Ọlọrun pè lati fi iná jà, o si jó ibú nla nì run, o si jẹ apakan run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun ti OLÚWA Ọlọ́run fi hàn mí: OLÚWA Ọlọ́run ń pè fún ìdájọ́ pẹ̀lú iná; ó jó ọ̀gbun ńlá rún, ó sì jẹ ilẹ̀ run.