Amos 7:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó bi mí pé: “Amosi, kí ni o rí?” Mo bá dáhùn pé, “Okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé.” Ó ní: “Wò ó! Mo ti fi okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé sí ààrin àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi; n kò ní fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si wi fun mi pe, Amosi, kini iwọ ri? Emi si wipe, Okùn-ìwọn kan ti o run ni. Nigbana ni Oluwa wipe, Wò o, emi o fi okùn-ìwọn rirun kan le ilẹ lãrin Israeli enia mi: emi kì yio si tun kọja lọdọ wọn mọ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì bi mi pé, “Ámósì, kí ni ìwọ rí?” Mo dáhùn pé, “Okùn-ìwọ̀n.” Nígbà náà ni OLÚWA wí pé, “Wòó, Èmí ń gbé okùn-ìwọ̀n kalẹ láàárin àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi; Èmi kì yóò sì tún kọjá lọ́dọ̀ wọn mọ́